-
Ìjàpá àti Bàbá Oníkàn ní Ṣókí
Ní ìgbà kan, Ìjàpá jẹ́ ọ̀lẹ tí kò fẹ́ ṣiṣẹ́, kò fẹ́ ṣe nǹkankan. L’ọ́jọ́ kan, Ìjàpá ronú nípa nǹkan tí yóò ṣe láti gba oúnjẹ láìṣiṣẹ́. Ní ìgbà mìíràn, ó máa ń jẹun nílé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, nígbà yẹn, kò lè jẹun nílé ọ̀rẹ́ rẹ̀, torí pé gbogbo àwọn ìyàwó wọn tì lọ s’ọ́jà. Torí náà, ó lọ sí oko Bàbá Oníkàn láti jí ìgbá wọn. Ó dẹ̀rùba gbogbo àwọn ènìyàn t’ó wà nibẹ̀. Lẹ́hìn yẹn, wọ́n sá lọ.
Àwọn ènìyàn tí wọ́n ti sá lọ lọ s’ọ́dọ̀ Kábíyèsi láti rò fún Ọba nípa nǹkan t’ó ṣẹlẹ̀. Wọ́n sọ́ gbogbo rẹ̀ fún un. Ọba ronú nípa nǹkan tí yóò ṣe fún ìlú. Ó rí nǹkan tí wọ́n ní láti ṣe. Ó pe Ọ̀sanyìn Ẹlẹ́sẹ̀kan láti wá pa ẹni ti ó jí ìgbá l’ọ́dọ̀ wọn. Ní ìgbà tí Ìjàpá débẹ̀, gbogbo ènìyàn sá lọ, ṣùgbọ́n, Ọ̀sanyìn kò lè sá lọ torí pé ó ní ẹsẹ̀ kan ṣoṣo. Ó dúró gboingboin. Nígbàti Ìjàpá rò pé gbogbo ènìyàn ti sá lọ, ó lọ jí ìgbá. Ọ̀sanyìn dúro l’ẹ́hìn Ìjàpá, ó pa á o. Kábíyèsi sọ fún Ọ̀sanyìn pé ó lè ṣe nǹkankínkan tí ó bá fẹ́ pẹ̀lú òkú Ìjàpá. ‘Torí náà, Ọ̀sanyìn Ẹlẹ́sẹ̀kan gbé e lọ láti dín in, láti jẹ Ìjàpá. Àlọ́ yìí kọ́ wa pé a ní láti ní ìwà tó dára.
Ɔbenfo Ọbádélé-
90,548 Abibisika (Black Gold) Points
O káre l’áyé. O ṣe dáadáa.
-