-
Adì ńjẹkà, ó ḿmumi, ó ńgbé òkúta p -p-p mì, ó ní òun ò léhín; ìdérègbè tó léhínńgbé irin mì bí? The chicken eats corn, drinks water, even swallows small pebbles, and yet complains that it lacks teeth; does the goat that has teeth swallow steel? (One should be content with one’s lot.)
-
88,768 Abibisika (Black Gold) Points
O káre l’áyé!!! -
88,768 Abibisika (Black Gold) Points
Ẹni tí a bá ńdáṣọ fún kì í ka èèwò.
The person who is clothed by others does not list what he will not wear. (Those who depend on the charity of others must be satisfied with whatever they can get.-
Orogún ìyá ẹ-é dáṣọ fún ọ o ní kò balè; mélòó nìyá ẹ-é dá fún ọ tó fi kú? Your mother’s co-wife made a garment foryou, and you complain that it is not long enough; how many did your mother make for you before she died? (People dependent on charity should be grateful rather than difficult to please.)
-
88,768 Abibisika (Black Gold) Points
Ẹni tí a bá ṣe lóore tí kò dúpẹ́, bí a bá ṣe é níkà kò níí dùn ún.
The person who shows no gratitude when he or she is done a favor will feel no hurt when he or she is done an injury. (Ungrateful people deserve to be deliberately hurt.)-
Kí ni a ó ṣe fún ọmọ àlè tí yó peni ní baba? What could one do for a bastard that would induce him or her to call one ‘‘father’’? (A favor done for unworthy and ungrateful people is a favor done in vain.)
-
88,768 Abibisika (Black Gold) Points
Bí ọmọdé bá dúpẹ́ oore àná, a rí tòní gbà.
If a child expresses gratitude for yesterday’s favor, he will receive today’s. (The grateful person encourages others to do him more favors.)
-
-
Ẹni tó bá rántí ọjó ní ńṣe ọmọ òkú pèlé; ta ní j ṣe ọmọ eégún lóore? Those who gratefully remember past favors extend compassion to the survivors of the deceased; who would rather show compassion to the child of a masquerader ?( When a good person dies, the survivors inherit the good will of those who remember him or her well.)
-
88,768 Abibisika (Black Gold) Points
Èké kú, a gbẹ́lẹ̀ ó kan òkúta.
The devious person dies, and while digging his or her grave one strikes a rock. (Even the earth bears witness against the wicked.) -
88,768 Abibisika (Black Gold) Points
Ẹni tí a ṣe lóore tí kò dúpẹ́, bí ọlọ́ṣà-á kóni lẹ́rù ni.
A person for whom one does a favor but who shows no gratitude is like a robber who has stolen one’s goods. (Ingratitude is comparable to robbery.)
-
-
Bí èèyàn-án bá ṣeun ká sọ pé ó ṣeun; bí èèyàn-án bá ṣèèyàn ká sọ pé ó ṣèèyàn;nítorípé, ohun tí a ṣe, ó yẹ kó gbeni. If a person deserves gratitude, we should say that he deserves gratitude; if a person is kindly, we should say that he is kindly, because one should reap the rewards of one sactions. (A person’s goodness should be publicly acknowledged.)
-
88,768 Abibisika (Black Gold) Points
Bí oore bá pọ̀ lápọ̀jù, ibi ni ń dà.
If goodness is excessive, it becomes evil.
(There can be too much of even a good thing.) -
A kì í rójú ẹni puró móni.One does not look into the eyes of a person and still tell a lie against that person. (It is always easier to do evil to people who are absent.)
-
88,768 Abibisika (Black Gold) Points
Ojú kì í fẹ́nikù kó hu ibi.
The eyes do not, because they do not see one, engage in evil against one. (Never take advantage of people’s absence to do them ill.) -
Àìsí-ńlé ológbò, ilé dilé èkúté.The cat being away from home, the house becomes a domain for mice. (People will take advantage of any relaxation of supervision.)
-
88,768 Abibisika (Black Gold) Points
A kì í mọ alájá ká pè é ní títà.
One does not know the owner of a dog and yet announce that it is for sale. (One should safeguard the interests of those one knows, even in their absence. Compare the preceding and following entries.) -
Ẹni tí ó ṣe ojú kò da bí ẹni tó ṣe èhìn.The person who honors one in one’s presence is nothing like the person who honors one in one’s absence. (It is what people say of you or do on your behalf in your absence that matters.)
-
88,768 Abibisika (Black Gold) Points
Ṣàṣà èeyàn ní ń fẹ́ni lẹ́hìn bí a ò sí nílé; tajá tẹran ni ń fẹ́ni lójú ẹni.
Few people love one when one is absent; every dog and goat loves one when one is present. (Never trust that those who show you affection in your presence will express the same sentiments in your absence.) -
Aláṣọ dúdú lọ̀tá ayé; èèyàn bí àparò layé ńfẹ́. The person in black is begrudged by humankind; humankind loves people like partridges. (People love those they can take advantage of.)
-
88,768 Abibisika (Black Gold) Points
Má fi òdù fọ́ mi ní àdó; má fi ẹṣin tẹ̀ mí lágùntàn pa.
Do not break my tiny gourdlet with your large pot; do not use your horse to trample my sheep to death. (Do not take advantage of me, even though you are wealthier and more powerful than I.) -
A kì í re nísun lọ dà síbú.One does not collect water from a spring to dump in the deep. (Do not rob the poor to further enrich the wealthy.)
-
Àì dúp oore ànà mú ooré súnií ṣe.Failure to show gratitude for yesterday’s favor dissuades benefactors from extending favors. (If one shows no gratitude for previous kindnesses, one stops receiving favors. Compare 878.)
-
88,768 Abibisika (Black Gold) Points
Àṣetán ló níyì; a kì í dúpẹ́ aláṣekù.
Completing-a-job is what is appreciated; one does not express gratitude for something half done. (What is worth doing is worth finishing.) -
Àgbàká lèéfí ńgba igbó. It is completely that smoke fills the forest. (Whatever is worth doing is worth doing diligently and thoroughly.)
-
88,768 Abibisika (Black Gold) Points
Àgbẹ̀ roko roko, wọn kà ṣàì gbàgbé ewé kan sébè.
However thoroughly a farmer might weed his farm, he will not fail to overlook some
leaf on a mound. (No one can achieve perfection.) -
ẹ̀wà ìkákùré ò nà tán; awo ẹni ò lè ṣe awo rere tán. Ìkákùré bean does not stretch out completely; one’s charm cannot be absolutely infallible. (There is no absolute perfection anywhere.)
-
88,768 Abibisika (Black Gold) Points
Ẹni tí yóò pẹ̀gàn òrìṣà ni yóò pèé àfín kò fín tó; ó fẹ́ kó bó lára ni?
It is a person who wishes to scorn the òrìṣà who will say that the albino is not bleached enough; would the person prefer that the albino have no skin? (It is silly to find fault with perfection.) -
A kì í fi ọ̀nà odò han ikún. One does not show the squirrel the way to the river. (Telling someone what he or she already knows is silly.)
-
88,768 Abibisika (Black Gold) Points
Ọ̀ràn t’ó bá ṣe ojú ìlú ò fara sin.
Whatever happened in the presence of the whole town cannot be kept secret. (It is pointless to be secretive about something everybody already knows about.) -
Gba n gba-á dẹkùn, kedereé bẹ̀ ẹ́ wò: ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ ò sí níbẹ̀. A leopard is trapped in open space; clearsight gets a good look at it; the matter doesnot admit of secrets. (Once a secret is leaked, it can no longer be hidden.)
-
-
-
-
-
88,768 Abibisika (Black Gold) Points
@amalove805, note that pasting ẹ ẹ́ and ẹ̀ as well as ọ ọ́ and ọ̀ don’t show up correctly, so you have to type those in manually. O ṣé -
88,768 Abibisika (Black Gold) Points
That’s what the [Nana] Wilson [Nana] Baker Academy students are preparing for. We’ll invite you to the event! -
88,768 Abibisika (Black Gold) Points
It should be great! Boys vs. girls! Ìbàdàn vs. Èkó. It’ll be BlackNificent!!!
-