-
Ritual time, Ìṣẹ̀ṣe Làgbà. Offerings easily accepted
-
79,168 Abibisika (Black Gold) Points
L’ọ́jọ́ ìwájú a kò níí fi owó fún àwọn ọ̀tá wa láti bọ̀wọ̀ fún àwọn Òrìṣà, àti àwọn ará Ìwájú. Àṣẹ.
-
@obadelekambon Àṣẹ. I’m definitely looking for a way to make my Ọ̀ṣẹ̀ process all black. I asked about using emu in place of the gin for ọtí, I was told they are two different offerings. This bottle of tanqueray is just running out so I’m looking for Black owned, manufactured or at least sold ọtí. I bought this one following my Olúwó. Also need a black owned honey company. I’m glad that you mentioned this.
-
79,168 Abibisika (Black Gold) Points
@mufasashabazz Ọ̀kan nínú wọn nìkan l’ó ń jẹ́ ìṣẹ̀ṣe wa. Òmìíràn l’ó ń jẹ́ ayédẹ̀rú àṣà. Àṣà aládàmọ̀dì. Àṣà àmúlùmálà. Tí a bá ń sọ pé a ò lè júbà Òrìṣà àyàfi tí a bá yà sọ́dọ̀ àwọn òyìnbó k’á tó ṣe bẹ́ẹ̀, a ní láti bèèrè pé láti ìgbà wo? Nígbà wo ni irú òfin bẹ́ẹ̀yẹn bẹ̀rẹ̀? Kò sí níbẹ̀ k’áwọn ọ̀tá wa dé. Nítorí náà, a ni láti padà sí ìṣẹ̀ṣe t’ó ń jẹ́ àgbà ki ayédẹ̀rú àṣà tó dé. Ìṣẹ̀ṣe l’àgbà. Ayédẹ̀rú àṣà l’ọmọdé.
-
@obadelekambon You have a good point. As I study I learn that many of the things done today are adaptation, or evolutions of the practice, even pre colonial adaptations/evolutions. So I figured that that was the reason for some of the things added today. Just like the ẹsẹ Ifá library can grow, I thought other things could grow as well. I will definitely ask some questions about this though. I have thought about this in the past.
1 -
79,168 Abibisika (Black Gold) Points
Nǹkan lè yí padà nítòótọ́. Tèmi ni pé k’ó yí padà sí nǹkan t’ó wúlò fún àwa ènìyàn dúdú. Gẹ́gẹ́ bíi ẹnìkan lè yí i padà sí èyí t’ó fún àwọn òyìnbó ọ̀tá wa l’ówó (nítorí tí aláìronú), àwa náà lè yí i padà sí èyí t’ó ń ràn wá l’ọ́wọ́. Pàápàá jù lọ nígbà tí a mọ̀ pé nǹkan tí wọ́n ń ṣe kìí ṣe ìṣẹ̀ṣe. Kìí ṣe àṣà wa. Ó kàn jẹ́ èyí tí ẹnìkan bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ní ọgọ́rùnún ọdún sẹ́hìn. Tìwa fún wa l’ówó. Tìwọn fún wọn l’ówó.